1. Bukun le wa Oyeyemi Sweet-Melody

CAC Hymn V001

1. Bukun 'le wa at'ebi wa, at'ara wa/2ce
Ibukun orun, iranwo, Re,
Ibukun orun ko fi kari awa,
K'O fi fun wa o, l'aye l'orun o,
Baba orun

2. Tu wa lara, Alagbara, se 'toju wa/2c
Itunu Re, alafia Re,
Ike Re, K'O fi toju wa, ye,
Awa mbe O o, gbo adura wa,
Oba Ogo.

3. Baba fun wa l'Emi mimo at'agbara/2ce
Iranse orun, ebun lat'orun
Itunu Baba, k'o wonu okan wa,
K'o gbe 'nu wa o, k'o fun wa l'ayo,
Oba Orun.

4. Awa f'iyin at'ope fun Baba l'orun/2ce
Iyin fun 'ranwo, ope fun anu,
Ayo fun 'dasi ti a nri lojojo,
Ope fun O o, a tun juba Re,
Baba awa.

Amin