1. Ji Wo Kristian Oyeyemi Sweet-Melody

CAC HYMN 509

1. Ji, 'wo Kristian, k'o ki oro ayo
Ti a bi Olugbala araye;
Dide, k'o korin ife Qlorun
T'awon Angeli nko n'ijo kini;
Lat' odo won n'ihin na ti bere:
ihin Om'Olorun t'a bi s'aye.

2. 'Gba na l'a ran akede angeli;
T'a so f'awon olus'agutan pe,
“Mo mu 'hinrere Olugbala wa
T'a bi fun yin ati gbogbo aye,
Olorun mu l'eri Re se loni
A bi Olugbala, Krist' Oluwa.

3. Bi akede angel' na ti so tan,
Opolopo ogun orun si de;
Won nkorin ayo t'eti ko gbo ri,
Orin Aleluya gba orun kan,
Ogo ni f'Olorun l'oke orun,
Alafia at'ife s'eniyan.

4. A ba le ma ranti nigbagbogbo
Pe, 'fe Olorun l'o gba 'raye la,
K'a to 'se Jesu t'o ra wa pada,
Lat' ibuj' eran dor' agbelebu;
K'a toro or'-ofe k'a le te le,
Titi ao tun r'oju Re Qlorun.

5. Nigbana 'gba 'ba de orun lohun
A o korin ayo t'irapada;
Ogo Eni t'a bi fun wa loni,
Y'o ma ran yi wa ka titi laelae;
A o ma korin ife Re titi,
Oba angeli, Oba eniyan.

Amin