1. Ojo Nla Lojo Ti Mo Yan Oyeyemi Sweet-Melody

CAC HYMN 869

1. Ojo nla l'ojo ti mo yan
Olugbala l'Olorun mi;
O ye ki okan mi ma yo,
K'o si ro ihin na kale

Ojo nla l'ojo na
Ti Jesu we ese mi nu;
O ko mi ki nma gbadura
Ki nma sora, ki nsi ma yo,
Ojo nla l'ojo na
Ti Jesu we ese mi nu.

2. Ise igbala pari na,
Mo di t'Oluwa mi loni;
On l'o pe mi, ti mo si je,
Mo f'ayo j'ipe mimo na.

3. Eje mimo yi ni mo je
F'eni to ye lati feran:
Je k'orin didun kun 'le RE
Nigba mo ba nlo sin nibe

4. Simi, aiduro okan mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Tani je wipe aye dun,
Ju odo awon angeli?

5. 'Wo orun t o ngbo eje mi,
Y'o ma tun gbo lojojumo,
Tit' ojo t'emi mi y'o pin
Ni uno ma m'eje mi na se

Amin.