1. Ojo Sinmi At'ayo Oyeyemi Sweet-Melody

CAC HYMN 044

1. Ojo 'simi at'ayo
Ojo inu didun,
Itunu fun 'banuje
Ojo dida julo,
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re,
Nko Mimo, Mimo, Mimo,
S'Eni Metalokan.

2. L'ojo yi n'imole la,
Nigba dida aye,
Ati fun igbala wa,
Krist' jinde n'nu oku
L'ojo yi li Oluwa
Kan Emi t'orun wa,
Ojo Ologo julo
T'a tan 'mole pipe

3. Ebute abo ni O
Larin iji aye;
Ogba didara ni O
Nib'omi iye nsan
Orisun 'tura ni O
Laye aginju yi;
L'ori re, bi ni pisga
L'a nwo 'le ileri.

4. L'oni s'ilu t'ara nu
Ni manna t'orun nbo
Si ipejopo mimo
N'ipe fadaka ndun,
N'ibiti ihinrere
Ntan imole mimo
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara.

5. K'a r'ore-ofe titun
L'ojo 'simi wa yi
K'a si de 'simi t'o ku
F'awon alabukun,
Nibe k'a gbo 'hun soke
Si Baba at'Omo;
Ati si Emi Mimo
N'iyin Metalokan.

AMIN