CAC HYMN V07
1. Emi y'o san ore o f'Olorun mi)2x 2. E jek' asajoyo f'ope oni) 3. Emi y'o yin Jesu, Oba Ogo) 4. E je k'a fope han f'Olorun wa) Amin.
Eni da mi si o latesi wa )2x
Fun jije, fun mimu, t'o n b'asiri mi
Fun ipese lojojumo l'ona ara jaburata
Ko je k'aye yo mi, loju elegan, aye mi Dara
Emi y'o fore han f'Olorun mi.
Eni ba m'ore Re waka s'ope )2x
F'ori wa to dara, ti O nbukun fun wa
O fi'gbala da wa lola, O npese ohun gbogbo
Ko jek' awa segbe, loju elegan, O gbe wa ro o
Eni 'nu re ba dun je ko yo o.
Olu seun ara, O m'ayo mi kun )2x
O da mi lola o, O tun pe mi l'omo
O f'ohun atata le mi lowo, ohun ijinle to daju
Ko jek' eru ba mi, loju elegan o ye mi si o
Emi y'o yin Jesu, Oba ogo.
Eni da wa si o d'ojo oni )2x
O fun wa logbon o, O tun pe wa sagbo
Omo Igbala mura giri, ko ma foya rara rara
Duro ninu 'gbagbo, lojo aye re, a dara fun o
E jek'a f ope han f'Olorun wa.