- Jesu Yio Gba Elese Oyeyemi Sweet-Melody
CAC HYMN 398
1. Jesu y'o gba elese
Kede re fun gbogb' eda;
Awon ti won sako lo,
Awon ti won ti subu.
Ko l'orin, ko si tun ko
Kristi ngb' awon elese
Fi oto na ye won pe:
Kristi ngb' awon elese
2. Wa, y'o fun o ni 'simi;
Gbagbo, oro Re daju,
Y'o gba eni buru ju;
Kristi ngb' awon elese
3. Okan mi da mi lare,
Mo mo niwaju ofin;
Eni t'O ti we mi mo,
Ti san gbogbo 'gbese mi.
4. Kristi ngb' awon elese
An' emi to kun f'ese
O ti so mi di mimo;
Mo ba wo 'joba Orun;
Amin.