- Mo Yo Pupo Pe Baba Wa Orun Oyeyemi Sweet-Melody
CAC HYMN 478
1. Mo yo pupo pe Baba wa orun
So t'ife Re ninu 'we t'O fun mi,
Mo r'ohun 'yanu ninu Bibeli,
Eyi s'owon ju pe, Jesu fe mi.
Mo yo pupo pe Jesu fe mi,
Jesu fe mi, Jesu fe mi,
Mo yo pupo pe Jesu fe mi,
Jesu fe an'emi.
2. 'Gba mo gbagbe Re, ti emi sa lo,
O fe mi sibe, O wa mi kiri;
Mo yara pada s'apa anu Re,
'Gbati mo ranti pe Jesu fe mi.
3. Bi o se orin kan l'emi le ko,
'Gba mo r'Oba nla ninu ewa Re;
Eyi ni yo ma j'orin mi titi,
A! iyanu ni pe, Jesu fe mi.
4. Jesu fe mi, mo si mo pe mo f'E,
Ife lo mu wa r'okan mi pada
Ife lo m'U k'o ku l'ori igi
O da mi loju pe, Jesu fe mi.
5. Emi o ti se dahun b'a bi mi
Ohun ti ogo Oluwa mi je?
Emi mimo njeri nin'okan mi,
Ni igba gbogbo pe, Jesu fe mi.
6. Ni 'gbekele yi ni mo r'isimi,
Ni 'gbekele Krist' mo d'alabukun,
Satan damu sa kuro l'okan mi,
Nigba mo so fun pe, Jesu fe mi.
Amin.