- Olorun Wa Nbe Larin Wa Oyeyemi Sweet-Melody
CAC HYMN 347
1. Olorun wa mbe larin wa,
Lati bukun gbogbo wa,
Wo oju orun b'o ti su
Yo ro ojo ibukun;
K'o de Oluwa, a be O
Je k'ojo Ibukun de;
Awa nduro, awa nduro,
M'okan gbogbo wa soji
2. Olorun wa mbe larin wa
Ninu ile mimo yi,
Sugbon a nfe 'tura okan
At'opo or'ofe Re
3. Olorun wa mbe larin wa,
K'a mu ebe wa t'O wa,
Ki ife Re ba le gberan
Lati m'okan wa gbona.
4. Jesu fi 'bere wa fun wa,
B'a ti f' igbagbo kunle,
Jo si ferese anu Re
K'o tu 'bukun sori wa.
Amin.