1. Oluwa Ojo to Fun Wa Pin Oyeyemi Sweet-Melody

CAC HYMN 029

1. Oluwa, ojo to fun wa pin
Okunkun si de l'ase Re,
'Wo l'a korin owuro wa si,
Iyin Re y'o m'ale wa dun.

2. A dupe ti ijo Re ko sun,
B'aye ti nyi lo s'imole,
O si nsona ni gbogbo aye
Ko si simi t'osan-t'oru.

3. B'ile si ti nmo l'ojojumo,
Ni orile at'ekusu,
Ohun adura ko dake ri,
Be l'orin iyin ko dekun

4. Orun t'o wo fun wa, si ti la,
S'awon eda iwo-oorun,
Nigbakugba li enu si nso
Ise 'yanu Re di mimo

5. Be, Oluwa, lae n'Ijoba Re,
Ko dabi ijoba aye;
O duro, o si nse akoso,
Tit' eda Re o juba Re.

AMIN